O. Daf 35:15-28

O. Daf 35:15-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ. Pẹlu awọn àgabagebe ti iṣe ẹlẹya li apejẹ, nwọn npa ehin wọn si mi. Oluwa iwọ o ti ma wò pẹ to? yọ ọkàn mi kuro ninu iparun wọn, ẹni mi kanna lọwọ awọn kiniun. Emi o ṣọpẹ fun ọ ninu ajọ nla: emi o ma yìn ọ li awujọ ọ̀pọ enia. Máṣe jẹ ki awọn ti nṣe ọta mi lodi ki o yọ̀ mi; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki awọn ti o korira mi li ainidi ki o ma ṣẹju si mi. Nitori ti nwọn kò sọ̀rọ alafia: ṣugbọn nwọn humọ ọ̀ran ẹ̀tan si awọn enia jẹjẹ ilẹ na. Nitotọ, nwọn ya ẹnu wọn silẹ si mi, nwọn wipe, A! ã! oju wa ti ri i! Eyi ni iwọ ti ri, Oluwa: máṣe dakẹ: Oluwa máṣe jina si mi. Rú ara rẹ soke, ki o si ji si idajọ mi, ati si ọ̀ran mi, Ọlọrun mi ati Oluwa mi. Ṣe idajọ mi, Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi ododo rẹ, ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o yọ̀ mi. Máṣe jẹ ki nwọn kí o wi ninu ọkàn wọn pe, A! bẹ̃li awa nfẹ ẹ: máṣe jẹ ki nwọn ki o wipe, Awa ti gbé e mì. Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si dãmu pọ̀, ti nyọ̀ si ifarapa mi: ki a fi itiju ati àbuku wọ̀ wọn ni aṣọ, ti ngberaga si mi. Jẹ ki nwọn ki o ma hó fun ayọ̀, ki nwọn ki o si ma ṣe inu-didùn, ti nṣe oju-rere si ododo mi: lõtọ ki nwọn ki o ma wi titi pe, Oluwa ni ki a ma gbega, ti o ni inu-didùn si alafia iranṣẹ rẹ̀. Ahọn mi yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ, ati ti iyìn rẹ ni gbogbo ọjọ.

O. Daf 35:15-28 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n ń yọ̀, wọ́n kó tì mí; pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran? Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí, gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun! Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan; láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́. Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí, má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín. Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn àfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn. Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí, wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!” O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́. OLUWA, má jìnnà sí mi. Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi, gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi! Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ; má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí! Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!” Má jẹ́ kí wọn wí pé, “A rẹ́yìn ọ̀tá wa.” Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi; kí ìdààmú bá wọn; bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi. Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mi máa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn, kí wọ́n máa wí títí ayé pé, “OLUWA tóbi, inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.” Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru.

O. Daf 35:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ; wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀. Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́. Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ wọ́n pa eyín wọn keke sí mi. Yóò ti pẹ́ tó OLúWA, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ? Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn, àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún. Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá; èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi. Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà. Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà! Ojú wa sì ti rí i.” Ìwọ́ ti rí i OLúWA; má ṣe dákẹ́! Olúwa má ṣe jìnnà sí mi! Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi, àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi! Ṣe ìdájọ́ mi, OLúWA Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi! Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!” Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.” Kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi. Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú; kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni OLúWA, sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.” Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.