O. Daf 35:1-8
O. Daf 35:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà. Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi. Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ. Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi. Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn. Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn. Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi. Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
O. Daf 35:1-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí; gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà! Gbá asà ati apata mú, dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́! Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi! Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi, kí wọn ó tẹ́! Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú, kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn! Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́, kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ! Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀, kí angẹli OLUWA máa lépa wọn! Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí, wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì, jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn; jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!
O. Daf 35:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà! Di asà àti àpáta mú, kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi! Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi. Sọ fún ọkàn mi pé, “Èmi ni ìgbàlà rẹ.” Kí wọn kí ó dààmú, kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú; kí a sì mú wọn padà, kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi. Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́, kí angẹli OLúWA kí ó máa lé wọn kiri. Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́, kí angẹli OLúWA kí ó máa lépa wọn! Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi. Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì. Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.