O. Daf 32:1-7
O. Daf 32:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun awọn ti a dari irekọja wọn jì, ti a bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si. Nigbati mo dakẹ, egungun mi di gbigbo nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ. Nitori li ọsan ati li oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara: omi ara mi si dabi ọdá-ẹ̀run. Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì. Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri.
O. Daf 32:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn, tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀. Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ó rẹ̀ mí wá láti inú, nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà. Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà; gbogbo agbára mi ló lọ háú, bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ. Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,” o sì dáríjì mí. Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ; ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá, kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìwọ ni ibi ìsásí mi; o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro; o sì fi ìgbàlà yí mi ká.
O. Daf 32:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn. Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún OLúWA,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela. Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a lè rí ọ; nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi; ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu; ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.