O. Daf 30:1-12
O. Daf 30:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi. Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da. Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho. Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀. Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ. Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai. Oluwa, nipa oju-rere rẹ, iwọ ti mu òke mi duro ṣinṣin: nigbati iwọ pa oju rẹ mọ́, ẹnu yọ mi. Emi kigbe pè ọ, Oluwa; ati si Oluwa li emi mbẹ̀bẹ gidigidi. Ere kili o wà li ẹ̀jẹ mi, nigbati mo ba lọ sinu ihò? erupẹ ni yio ma yìn ọ bi? on ni yio ma sọ̀rọ otitọ rẹ bi? Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi. Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure. Nitori idi eyi ni ki ogo mi ki o le ma kọrin si ọ, ki o má si ṣe dakẹ. Oluwa Ọlọrun mi, emi o ma fi iyìn fun ọ lailai.
O. Daf 30:1-12 Yoruba Bible (YCE)
N óo yìn ọ́, OLUWA, nítorí pé o ti yọ mí jáde; o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́, o sì wò mí sàn. OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí wọ́n ti wọ inú kòtò. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀, kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀. Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀, ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀; eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́, ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀. Nígbà tí ara rọ̀ mí, mo wí ninu ọkàn mi pé, kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae. Nípa ojurere rẹ, OLUWA, o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá; ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi, ìdààmú dé bá mi. Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA, OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀. Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú? Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò? Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́? Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ? Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́. O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó, o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi, o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀, kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́. OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae.
O. Daf 30:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kókìkí i rẹ, OLúWA, nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí. OLúWA Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ ìwọ sì ti wò mí sàn. OLúWA, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò. Kọ orin ìyìn sí OLúWA, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́. Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀. Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé, “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.” Nípa ojúrere rẹ, OLúWA, ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára; ìwọ pa ojú rẹ mọ́, àyà sì fò mí. Sí ọ OLúWA, ni mo ké pè é; àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú: “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi? Eruku yóò a yìn ọ́ bí? Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ? Gbọ́, OLúWA, kí o sì ṣàánú fún mi; ìwọ OLúWA, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.” Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí, nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ OLúWA Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.