O. Daf 3:3-6
O. Daf 3:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin, Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.
O. Daf 3:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká kò le bà mí lẹ́rù.
O. Daf 3:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, OLúWA; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. OLúWA ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí OLúWA ni ó ń gbé mi ró. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.