O. Daf 29:1-11
O. Daf 29:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi fún OLúWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, Ẹ fi fún OLúWA, ògo àti alágbára. Fi fún OLúWA, àní ògo orúkọ rẹ̀; sin OLúWA nínú ẹwà ìwà mímọ́. Ohùn OLúWA n ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, OLúWA san ara. Ohùn OLúWA ní agbára; ohùn OLúWA kún fún ọláńlá. Ohùn OLúWA fa igi kedari; OLúWA náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya. Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù, àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré. Ohùn OLúWA ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà Ohùn OLúWA ń mi aginjù. OLúWA mi aginjù Kadeṣi. Ohùn OLúWA ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí, ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò. Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!” OLúWA jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; OLúWA jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé. Kí OLúWA fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
O. Daf 29:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀. Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla. Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya. O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere. Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná, Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi. Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀. Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai. Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀.
O. Daf 29:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA, ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀, ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. Ohùn OLUWA lágbára, ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá. Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari, OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni. Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù, ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó. Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá. Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀; OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi. Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí, a máa wọ́ ewé lára igi oko; gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀. OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi; OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae. OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára; OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.