O. Daf 28:1-9
O. Daf 28:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ, Oluwa, apata mi li emi o kigbe pè, máṣe dakẹ si mi; bi iwọ ba dakẹ si mi, emi o dabi awọn ti o lọ sinu ihò. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi, nigbati mo ba nkigbe pè ọ, nigbati mo ba gbé ọwọ mi soke siha ibi-mimọ́ jùlọ rẹ. Máṣe fà mi lọ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ti nsọ̀rọ alafia si aladugbo wọn, ṣugbọn ìwa-ìka mbẹ̀ li ọkàn wọn. Fi fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, ati gẹgẹ bi ìwa buburu ete wọn, fi fun wọn nipa iṣẹ ọwọ wọn, fi ère wọn fun wọn. Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró. Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i. Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀. Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.
O. Daf 28:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA, ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi. Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́; tí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ìhà ilé mímọ́ rẹ. Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú, pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ọ̀rọ̀ alaafia, ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn. San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn; san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí, wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀, kò sì ní gbé wọn dìde mọ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA ni agbára ati asà mi, òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé; ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀; mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀; òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀. Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA, kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ. Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn, kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.
O. Daf 28:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ OLúWA, mo ké pe àpáta mi; Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ. Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn. San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn; gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn; kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLúWA sí, tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kì yóò sì gbé wọn ró mọ́. Alábùkún fún ni OLúWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLúWA ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un. OLúWA ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀. Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ; di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.