O. Daf 27:5-7
O. Daf 27:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa. Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn.
O. Daf 27:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́; ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.
O. Daf 27:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLúWA. Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! OLúWA, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn