O. Daf 27:3-6
O. Daf 27:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le. Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.

O. Daf 27:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.
O. Daf 27:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLúWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà OLúWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLúWA.