O. Daf 26:1-12
O. Daf 26:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀. Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò. Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ. Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle. Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko. Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa. Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ. Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ. Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ. Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o ma rìn ninu ìwatitọ mi: rà mi pada, ki o si ṣãnu fun mi. Ẹsẹ mi duro ni ibi titẹju: ninu awọn ijọ li emi o ma fi ibukún fun Oluwa.
O. Daf 26:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Dá mi láre, OLUWA, nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn, mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì. Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò; yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́, mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn. N kò jókòó ti àwọn èké, n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn; mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi, n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA, mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè, mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ. OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé, ati ibi tí ògo rẹ wà. Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn, àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé; rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi. Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA.
O. Daf 26:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣe ìdájọ́ mi, OLúWA, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLúWA Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀. Wádìí mi wò, Ìwọ OLúWA, kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò; Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé; Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó. Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká OLúWA. Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Háà OLúWA, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà. Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́; rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi. Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún OLúWA.