O. Daf 25:8-10
O. Daf 25:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na. Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀. Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́.
O. Daf 25:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Olóore ati olódodo ni OLÚWA, nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́, a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́, fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.
O. Daf 25:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní OLúWA: nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo ipa ọ̀nà OLúWA ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.