O. Daf 25:1-22
O. Daf 25:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi. Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì. Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ. Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo. Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ: Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na. Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀. Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́. Nitori orukọ rẹ, Oluwa, dari ẹ̀ṣẹ mi jì, nitori ti o tobi. Ọkunrin wo li o bẹ̀ru Oluwa? on ni yio kọ́ li ọ̀na ti yio yàn. Ọkàn rẹ̀ yio joko ninu ire, irú-ọmọ rẹ̀ yio si jogun aiye. Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀. Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na. Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi. Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka. Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ. Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ. Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
O. Daf 25:1-22 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé, má jẹ́ kí ojú ó tì mí; má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ; àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi; ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo. OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́. Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi, tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi; ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí oore rẹ. Olóore ati olódodo ni OLÚWA, nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́, a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́, fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ. Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà. Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo, nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní, ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí; má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí, nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́, nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọrun, ra Israẹli pada, kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.
O. Daf 25:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí. Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLúWA, kọ mi ní ipa tìrẹ; ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́. Rántí, OLúWA àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́ Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjá mi; gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! OLúWA. Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní OLúWA: nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo ipa ọ̀nà OLúWA ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́. Nítorí orúkọ rẹ, OLúWA, dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi. Àwọn wo ni ó bẹ̀rù OLúWA? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn. Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà. OLúWA fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ OLúWA, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà. Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi. Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì. Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn. Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi. Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́. Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!