O. Daf 25:1-10
O. Daf 25:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi. Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì. Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ. Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo. Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ: Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na. Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀. Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́.
O. Daf 25:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé, má jẹ́ kí ojú ó tì mí; má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ; àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi; ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo. OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́. Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi, tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi; ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí oore rẹ. Olóore ati olódodo ni OLÚWA, nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́, a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀. Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́, fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.
O. Daf 25:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí. Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLúWA, kọ mi ní ipa tìrẹ; ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́. Rántí, OLúWA àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́ Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjá mi; gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! OLúWA. Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní OLúWA: nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo ipa ọ̀nà OLúWA ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.