O. Daf 22:16-18
O. Daf 22:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ. Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn. Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi.
Pín
Kà O. Daf 22O. Daf 22:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá; àwọn aṣebi dòòyì ká mi; wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya. Mo lè ka gbogbo egungun mi wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.
Pín
Kà O. Daf 22O. Daf 22:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀ Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi. Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
Pín
Kà O. Daf 22