O. Daf 22:12-31
O. Daf 22:12-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka. Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu. A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi. Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú. Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ. Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn. Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi. Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ. Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì. Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere. Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ, Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli. Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́. Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai: Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀. Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède. Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye. Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa. Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi.
O. Daf 22:12-31 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù, wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára. Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun, bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù. Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé; ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu; o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá; àwọn aṣebi dòòyì ká mi; wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya. Mo lè ka gbogbo egungun mi wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi! Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́! Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá! Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù! N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi; láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́: Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín! Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un, ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́; kò sì ṣá wọn tì, bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn, ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é. Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan; n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA. Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó; àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín! Kí ẹ̀mí wọn ó gùn! Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWA wọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀; gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo sì júbà níwájú rẹ̀. Nítorí OLUWA ló ni ìjọba, òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀; gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọ ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀, àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè. Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín; àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, pé, “OLUWA ló ṣe é.”
O. Daf 22:12-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká. Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀ Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi. Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé. Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, má ṣe jìnnà sí mi; Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi! Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré. Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLúWA, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli! Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀ tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá OLúWA yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé! Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí OLúWA, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀, Nítorí ìjọba ni ti OLúWA. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín; a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa OLúWA, Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé, òun ni ó ṣe èyí.