O. Daf 22:1-5
O. Daf 22:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi? Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ. Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do. Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn. Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu.
O. Daf 22:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀, tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́? Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án, ṣugbọn o ò dáhùn; mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́, o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́. Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé; wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.
O. Daf 22:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi? Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó; Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n. Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.