O. Daf 22:1-18
O. Daf 22:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi? Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ. Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do. Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn. Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu. Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia. Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe, Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i. Ṣugbọn iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu wá: iwọ li o mu mi wà li ailewu, nigbati mo rọ̀ mọ́ ọmu iya mi. Iwọ li a ti fi mi le lọwọ lati inu iya mi wá: iwọ li Ọlọrun mi lati inu iya mi wá. Máṣe jina si mi; nitori ti iyọnu sunmọ etile; nitoriti kò si oluranlọwọ. Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka. Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu. A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi. Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú. Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ. Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn. Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi.
O. Daf 22:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀, tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́? Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án, ṣugbọn o ò dáhùn; mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́, o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́. Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé; wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n. Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi; wọ́n sì ń mi orí pé, “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́; kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là, ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!” Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi; ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú. Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́; ìwọ ni Ọlọrun mi láti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi. Má jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu wà nítòsí, kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́. Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù, wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára. Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun, bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù. Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé; ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu; o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá; àwọn aṣebi dòòyì ká mi; wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya. Mo lè ka gbogbo egungun mi wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.
O. Daf 22:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi? Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó; Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n. Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n. Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé. “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLúWA; jẹ́ kí OLúWA gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.” Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú; ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi. Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá, nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká. Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀ Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi. Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.