O. Daf 20:1-5
O. Daf 20:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ. Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá. Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ. Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ. Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ.
O. Daf 20:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́. Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá, yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ, yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ. Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ, yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ. Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun, ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀; OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.
O. Daf 20:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí OLúWA kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.