O. Daf 18:31-40
O. Daf 18:31-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn. Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi. Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi. Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run.
O. Daf 18:31-40 Yoruba Bible (YCE)
Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA? Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa? Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí, tí ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró, ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi, n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n, n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde, wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi. O gbé agbára ogun wọ̀ mí; o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi, mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
O. Daf 18:31-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe OLúWA? Ta ní àpáta bí kò ṣe OLúWA wa? Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá. Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀. Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n. Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi. Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.