O. Daf 148:1-4
O. Daf 148:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga. Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ. Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.
O. Daf 148:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ yìn ín lókè ọ̀run. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀. Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ; yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.
O. Daf 148:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ìyìn fún OLúWA. Ẹ fi ìyìn fún OLúWA láti ọ̀run wá, Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.