O. Daf 143:7-12
O. Daf 143:7-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, yára dá mi lóhùn! Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin! Má fara pamọ́ fún mi, kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú. Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀, nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn, nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; ìwọ ni mo sá di. Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi. Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́. Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí; ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú. Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi, kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.
O. Daf 143:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò. Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ. Oluwa, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: ọdọ rẹ ni mo sa pamọ́ si. Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju. Oluwa, sọ mi di ãye nitori orukọ rẹ: ninu ododo rẹ mu ọkàn mi jade ninu iṣẹ́. Ati ninu ãnu rẹ ke awọn ọta mi kuro, ki o si run gbogbo awọn ti nni ọkàn mi lara: nitori pe iranṣẹ rẹ li emi iṣe.
O. Daf 143:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dá mi lóhùn kánkán, OLúWA; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ. Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, OLúWA, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ. Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Nítorí orúkọ rẹ, OLúWA, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà. Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò, run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára, nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.