O. Daf 139:3-16
O. Daf 139:3-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ. Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata. Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi. Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ. Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ? Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi. Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju. Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.
O. Daf 139:3-16 Yoruba Bible (YCE)
O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn; o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi, ó ga jù, ojú mi kò tó o. Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀! Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá, kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí, níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú. Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi, òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ; òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi, ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́; ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! O mọ̀ mí dájú. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
O. Daf 139:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, OLúWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun; Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú. Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.” Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ. Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi. Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.