O. Daf 139:17-19
O. Daf 139:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to! Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ. Ọlọrun iba jẹ pa enia buburu nitõtọ: nitorina kuro lọdọ mi ẹnyin ọkunrin ẹ̀jẹ.
O. Daf 139:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi! Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ; nígbà tí mo bá sì jí, ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà. Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú, kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.
O. Daf 139:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó! Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye: nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀. Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.