O. Daf 139:15-16
O. Daf 139:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.
O. Daf 139:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
O. Daf 139:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.