O. Daf 133:1-3
O. Daf 133:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
KIYESI i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati ma jumọ gbe ni irẹpọ̀. O dabi ororo ikunra iyebiye li ori, ti o ṣàn de irungbọn, ani irungbọn Aaroni: ti o si ṣàn si eti aṣọ rẹ̀; Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.
O. Daf 133:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ó dára, ó sì dùn pupọ, bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀. Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí, tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n; bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni, àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀. Ó dàbí ìrì òkè Herimoni, tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni. Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun, àní, ìyè ainipẹkun.
O. Daf 133:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀. Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí, tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni: tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀; Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní OLúWA gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé.