O. Daf 132:11-12
O. Daf 132:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ. Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai.
O. Daf 132:11-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi, èyí tí kò ní yipada; ó ní, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn, àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”
O. Daf 132:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ti búra nítòótọ́ fún Dafidi: Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.