O. Daf 119:65-80
O. Daf 119:65-80 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ. Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ. Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ. Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ. Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi. Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ. Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi.
O. Daf 119:65-80 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani, ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi, ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi, fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè, nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga, nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí; ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá, kí wọ́n lè mọ òfin rẹ. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé, kí ojú má baà tì mí.
O. Daf 119:65-80 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA. Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ. Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ. OLúWA Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi mọ, OLúWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú. Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ. Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ. Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí.