O. Daf 119:33-48
O. Daf 119:33-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.
O. Daf 119:33-48 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ, n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ, nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ, kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ, àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ, sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ! Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn, nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà, nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ, nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
O. Daf 119:33-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ mi, OLúWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn. Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára. Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLúWA, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ; Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé. Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí, Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn. Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.