O. Daf 119:33-40
O. Daf 119:33-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.
O. Daf 119:33-40 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ, n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ, nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ, kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ, àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ, sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
O. Daf 119:33-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ mi, OLúWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn. Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára. Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.