O. Daf 119:137-160

O. Daf 119:137-160 Bibeli Mimọ (YBCV)

Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ. Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ. Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ. Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai.

O. Daf 119:137-160 Yoruba Bible (YCE)

Olódodo ni ọ́, OLUWA, ìdájọ́ rẹ sì tọ́. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ, òtítọ́ patapata ni. Mò ń tara gidigidi, nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin, mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi, sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Òdodo rẹ wà títí lae, òtítọ́ sì ni òfin rẹ. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi, ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae, fún mi ní òye kí n lè wà láàyè. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́, OLUWA, dá mi lóhùn; n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Mo ké pè ọ́; gbà mí, n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́; mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru, kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí; wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA, òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ. Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ, pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí, nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú, nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀, ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra, nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó! Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.

O. Daf 119:137-160 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Olódodo ni ìwọ OLúWA ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé. Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá. Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ. Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀. Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi, Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òye kí èmi lè yè. Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn OLúWA, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́. Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, OLúWA, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ. Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, OLúWA; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ. Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.