O. Daf 119:121-128
O. Daf 119:121-128 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.
O. Daf 119:121-128 Yoruba Bible (YCE)
Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ, má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ, má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ, ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí, fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.
O. Daf 119:121-128 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára. Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ. Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, OLúWA; nítorí òfin rẹ ti fọ́. Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ, Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.