O. Daf 119:105-112
O. Daf 119:105-112 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.
O. Daf 119:105-112 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi, òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ, pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ, sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo, ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae, nítorí pé òun ni ayọ̀ mi. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo, àní, títí dé òpin.
O. Daf 119:105-112 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ. A pọ́n mi lójú gidigidi; OLúWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ OLúWA, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. Òfin rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi. Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.