O. Daf 119:1-5
O. Daf 119:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!
O. Daf 119:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n, àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Ìbá ti dára tó tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!
O. Daf 119:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLúWA, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!