O. Daf 119:1-176

O. Daf 119:1-176 Bibeli Mimọ (YBCV)

IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ. Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́. Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ: Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi. Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ. Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ. Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi. Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi. Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi. Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ. Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ. Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ. Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ. Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi. Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ. Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi. Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu? Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ. Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi? Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ. Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ. Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ. Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́. Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi. Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo. Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin. Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ. Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́. Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe. Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ. Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ. Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi. Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́. Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ. Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ. Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ. Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi. Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ. Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.

O. Daf 119:1-176 Yoruba Bible (YCE)

Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n, àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Ìbá ti dára tó tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ! Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́, bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́, má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ, má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ! Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́, bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ, n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ, n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ, kí n lè wà láàyè, kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu tí ó wà ninu òfin rẹ. Àlejò ni mí láyé, má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún, tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi, nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́. Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi, sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi, àwọn ni olùdámọ̀ràn mi. Mo di ẹni ilẹ̀, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. La òfin rẹ yé mi, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́, mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìwà èké jìnnà sí mi, kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ. Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́, mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ. Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó tì mí. N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́, nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i. OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ, n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ, nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ, kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ, àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ, sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ! Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn, nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà, nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ, nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ, èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé: ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi, ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́, OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru, nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú, tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ, lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru; OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi: Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní; mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ, ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi, mo yipada sí ìlànà rẹ; mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi, n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́, nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí, àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani, ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi, ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ. Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi, fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ. Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè, nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga, nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí; ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá, kí wọ́n lè mọ òfin rẹ. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé, kí ojú má baà tì mí. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi; ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ. Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?” Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì, sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi? Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́. Gbogbo òfin rẹ ló dájú; ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran; o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi, ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ, nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí; nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí, wọ́n fẹ́ pa mí run, ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán, àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ! Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ, nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ, nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. N kò rin ọ̀nà ibi kankan, kí n lè pa òfin rẹ mọ́. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ, nítorí pé o ti kọ́ mi. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ, ó dùn ju oyin lọ. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye, nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké. Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi, òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ, pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ, sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo, ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ. Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae, nítorí pé òun ni ayọ̀ mi. Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo, àní, títí dé òpin. Mo kórìíra àwọn oníyèméjì, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi, mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi, kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè, má sì dójú ìrètí mi tì mí. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu, kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀, nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin, nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ, mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ, má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ, má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ, ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí, fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké. Òfin rẹ dára, nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀, a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ, nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore bí o ti máa ń ṣe sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan, kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ; kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò, nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́. Olódodo ni ọ́, OLUWA, ìdájọ́ rẹ sì tọ́. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ, òtítọ́ patapata ni. Mò ń tara gidigidi, nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin, mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi, sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Òdodo rẹ wà títí lae, òtítọ́ sì ni òfin rẹ. Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi, ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ. Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae, fún mi ní òye kí n lè wà láàyè. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́, OLUWA, dá mi lóhùn; n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Mo ké pè ọ́; gbà mí, n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ. Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́; mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ. N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru, kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí; wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA, òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ. Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ, pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí, nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú, nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀, ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra, nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó! Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae. Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí, ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA, mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gidigidi. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ; gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA, fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ, pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ, nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA; òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́, sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù; wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí, nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.

O. Daf 119:1-176 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLúWA, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́! Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo. Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀. Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀: Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ Ìyìn ni fún OLúWA; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ. Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ. La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé; Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi. Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ. Òfin rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi. Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ. Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ. Èmi yára di òfin rẹ mú. OLúWA má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí. Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀. Kọ́ mi, OLúWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn. Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára. Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLúWA, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ; Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé. Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí, Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn. Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀. Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí. Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́. Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ. Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLúWA, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn. Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀. Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé. Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLúWA, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́. Ìwọ ni ìpín mi, OLúWA: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ. Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ. Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ OLúWA Kọ́ mi ní òfin rẹ. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA. Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ. Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ. OLúWA Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi mọ, OLúWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú. Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ. Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ. Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí. Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ. Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí? Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ. Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé: ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí. Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ. Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́. OLúWA Ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin. Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́. Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́ Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ. Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni. OLúWA Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá. Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé. Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi. Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi! Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́. OLúWA Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ. A pọ́n mi lójú gidigidi; OLúWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ OLúWA, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. Òfin rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi. Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin. OLúWA Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ. Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́! Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí. Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ. Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni. Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀. Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ. OLúWA Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára. Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ. Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, OLúWA; nítorí òfin rẹ ti fọ́. Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ, Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú. OLúWA Òfin rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè. Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ. Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ. Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi. Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́. Olódodo ni ìwọ OLúWA ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé. Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá. Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ. Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀. Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi, Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òye kí èmi lè yè. Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn OLúWA, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́. Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, OLúWA, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ. Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, OLúWA; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ. Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀. Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, OLúWA, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ. Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀ Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi. Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, OLúWA; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLúWA, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi. Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró. Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

O. Daf 119:1-176

O. Daf 119:1-176 YBCVO. Daf 119:1-176 YBCV