O. Daf 119:1-10
O. Daf 119:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.
O. Daf 119:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n, àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Ìbá ti dára tó tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ! Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́, bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́, má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ, má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
O. Daf 119:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLúWA, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́! Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo. Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀. Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀: Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.