O. Daf 115:1-8
O. Daf 115:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ. Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi? Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u. Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia. Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran. Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun. Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade. Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
O. Daf 115:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa, orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé, níbo ni Ọlọrun wa wà? Ọlọrun wa wà ní ọ̀run, ó ń ṣe ohun tí ó wù ú. Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn. Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó, wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin. Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.
O. Daf 115:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kì í ṣe fún wa, OLúWA kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ. Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú. Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni, Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.