O. Daf 108:1-5
O. Daf 108:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn. Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu. Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède. Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye.
O. Daf 108:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun ọkàn mi dúró ṣinṣin. N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu! Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan, n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun, kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé.
O. Daf 108:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin Jí ohun èlò orin àti haapu èmi ó jí ní kùtùkùtù Èmi ó yìn ọ́, Ọlọ́run, nínú àwọn orílẹ̀-èdè èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀ Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.