O. Daf 107:29-32
O. Daf 107:29-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.
O. Daf 107:29-32 Yoruba Bible (YCE)
Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan, kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.
O. Daf 107:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́; Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ, Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.