O. Daf 106:43-48
O. Daf 106:43-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn. O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
O. Daf 106:43-48 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i, OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn, nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá, ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa, kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!”
O. Daf 106:43-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn; Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn. Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú. Gbà wá, OLúWA Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí, láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ. Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.