O. Daf 106:1-48

O. Daf 106:1-48 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn? Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo. Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò. Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ. Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu. Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa. Ṣugbọn o gbà wọn là nitori orukọ rẹ̀, ki o le mu agbara rẹ̀ nla di mimọ̀. O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju. O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì. Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù. Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀. Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀. Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀. O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn. Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa. Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ. Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu. Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà. Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko. Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti. Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa. Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn. Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa. Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju: Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni. Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú. Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn. Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá. A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai. Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn: Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ. Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn: Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn. Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn. Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa. Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ. Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn. Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn. Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn. Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn. O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 106:1-48 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán? Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́, àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa, a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti, wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ, wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀; kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ, ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn, ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn, ẹyọ ẹnìkan kò sì là. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, wọ́n sì kọrin yìn ín. Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀, wọ́n sì dán Ọlọrun wò. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè, ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n. Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó, ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì, ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀. Iná sọ láàrin wọn, ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu, wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà. Wọ́n gbé ògo Ọlọrun fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti, ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu, ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà, wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn, wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀, ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú, àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn, àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró. A sì kà á kún òdodo fún un, láti ìrandíran títí lae. Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba, wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose, nítorí wọ́n mú Mose bínú, ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn, ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn. Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn, èyí sì fa ìpalára fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin, ati ti àwọn ọmọbinrin wọn, tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani; wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́. Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè. Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀. Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí. Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára, wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn. Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i, OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn, nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá, ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa, kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!”

O. Daf 106:1-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Yin OLúWA! Ẹ fi ìyìn fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí tí ó ṣeun; Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára OLúWA, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀? Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́. Rántí mi, OLúWA, Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n, Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo. Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe, àwa ti ṣe ohun tí kò dá a, a sì ti hùwà búburú Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀ O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn. Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ. Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí OLúWA. Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀ Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú. Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin. Wọ́n pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti, Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́. Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́. Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí OLúWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù, Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn. Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀ Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn. Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá. Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀ Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn. Nígbà náà ni OLúWA bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀ Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn; Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn. Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú. Gbà wá, OLúWA Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí, láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ. Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.