O. Daf 106:1-15

O. Daf 106:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán? Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́, àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa, a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti, wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ, wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀; kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ, ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn, ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn, ẹyọ ẹnìkan kò sì là. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, wọ́n sì kọrin yìn ín. Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀, wọ́n sì dán Ọlọrun wò. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè, ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.

O. Daf 106:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Yin OLúWA! Ẹ fi ìyìn fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí tí ó ṣeun; Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára OLúWA, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀? Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́. Rántí mi, OLúWA, Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n, Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo. Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe, àwa ti ṣe ohun tí kò dá a, a sì ti hùwà búburú Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀ O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn. Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ. Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.