O. Daf 104:24-28
O. Daf 104:24-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ. Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla. Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀. Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn. Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn.
O. Daf 104:24-28 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀, ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá, nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ, ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò, fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ, nígbà tí o bá la ọwọ́, wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.
O. Daf 104:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, OLúWA! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye ohun alààyè tí tóbi àti kékeré. Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó jọ; nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.