O. Daf 104:10-15
O. Daf 104:10-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá; Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.
O. Daf 104:10-15 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.
O. Daf 104:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè. Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn. Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka. Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá: Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.