O. Daf 103:11-13
O. Daf 103:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.
O. Daf 103:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.