O. Daf 102:12-28

O. Daf 102:12-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ni yio duro lailai; ati iranti rẹ lati iran dé iran. Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de. Nitori ti awọn iranṣẹ rẹ ṣe inu didùn si okuta rẹ̀, nwọn si kãnu erupẹ rẹ̀. Bẹ̃li awọn keferi yio ma bẹ̀ru orukọ Oluwa, ati gbogbo ọba aiye yio ma bẹ̀ru ogo rẹ. Nigbati Oluwa yio gbé Sioni ró, yio farahan ninu ogo rẹ̀. Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn. Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa. Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye; Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ; Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu. Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa. O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru. Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ. Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ, Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ. Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin. Awọn ọmọ awọn iranṣẹ rẹ yio duro pẹ, a o si fi ẹsẹ iru-ọmọ wọn mulẹ niwaju rẹ.

O. Daf 102:12-28 Yoruba Bible (YCE)

Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae, ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran. Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni, nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó. Àkókò tí o dá tó. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ, àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́, yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀. Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní, kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn. Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀, kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA, pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀, láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé; láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn, ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀. Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni, kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn, láti sin OLUWA. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́, ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́, ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.” Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae; gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ, o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ; wọn yóo sì di ohun ìpatì. Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà, ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin. Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé; bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

O. Daf 102:12-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, ni yóò dúró láéláé; ìrántí rẹ láti ìran dé ìran. Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni, nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i; àkókò náà ti dé. Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ; wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ. Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ OLúWA, gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ. Torí tí OLúWA yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀. Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní; kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn. Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin OLúWA: “OLúWA wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé, Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.” Kí a lè sọ orúkọ OLúWA ní Sioni àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn OLúWA. Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú. Èmi sì wí pé; “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì. Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin. Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́; a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”