O. Daf 101:1-8
O. Daf 101:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o kọrin ãnu ati ti idajọ: Oluwa, si ọ li emi o ma kọrin. Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé. Emi ki yio gbé ohun buburu siwaju mi: emi korira iṣẹ awọn ti o yapa, kì yio fi ara mọ mi. Aiya ṣiṣo yio kuro lọdọ mi: emi kì yio mọ̀ enia buburu. Ẹnikẹni ti o ba nsọ̀rọ ẹnikeji rẹ̀ lẹhin, on li emi o ke kuro: ẹniti o ni ìwo giga ati igberaga aiya, on li emi kì yio jẹ fun. Oju mi yio wà lara awọn olõtọ, ki nwọn ki o le ma ba mi gbe: ẹniti o ba nrìn li ọ̀na pipé, on ni o ma sìn mi. Ẹniti o ba nṣe ẹ̀tan, kì o gbe inu ile mi: ẹniti o ba nsẹke kì yio duro niwaju mi. Lojojumọ li emi o ma run gbogbo enia buburu ilẹ na; ki emi ki o le ke gbogbo oluṣe buburu kuro ni ilu Oluwa.
O. Daf 101:1-8 Yoruba Bible (YCE)
N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo, OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí. N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n; nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi? N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi. N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi. Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun. N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan. Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi, n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi, n óo pa á run, n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè. N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí. Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi; bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi. Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà, n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.
O. Daf 101:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ OLúWA, èmi yóò máa kọrin ìyìn. Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé. Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún. Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí. Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi. Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà; èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú OLúWA.