O. Daf 1:2-3
O. Daf 1:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru. Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede.
O. Daf 1:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA, a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.
O. Daf 1:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin OLúWA àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.