O. Daf 1:1-6
O. Daf 1:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru. Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede. Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ. Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo. Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe.
O. Daf 1:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn, tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA, a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere. Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo. Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.
O. Daf 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin OLúWA àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere. Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù. Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo. Nítorí OLúWA ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.