Owe 6:27-35
Owe 6:27-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona? Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀. Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run. Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro. Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan. On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ.
Owe 6:27-35 Yoruba Bible (YCE)
Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà, kí aṣọ rẹ̀ má jó? Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná, kí iná má jó o lẹ́sẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí, kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà. Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi. Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje, ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án. Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí, ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun. Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà, ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae. Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru, kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san. Kò ní gba owó ìtanràn, ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.
Owe 6:27-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná? Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná? Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà. Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé. Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san. Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.