Owe 6:20-26
Owe 6:20-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ. Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ. Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye: Lati pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin buburu nì, lọwọ ahọn ìpọnni ajeji obinrin. Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara.
Owe 6:20-26 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́, má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo, kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ, bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ, bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀. Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè, láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú, ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀. Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ. Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.
Owe 6:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè. Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì. Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra. Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan, ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.